1 Èmi Alàgbà ni mo kọ ìwé yìí sí àyànfẹ́ arabinrin ati àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Kì í ṣe èmi nìkan ni mo fẹ́ràn rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ ni;
2 nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae.
3 Oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi Ọmọ Baba yóo wà pẹlu wa ninu òtítọ́ ati ìfẹ́.
4 Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba.
5 Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.
6 Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.