Juda 1:9-15 BM

9 Nígbà tí Mikaeli, olórí àwọn angẹli pàápàá ń bá Èṣù jiyàn, tí wọ́n ń jìjàdù òkú Mose, kò tó sọ ìsọkúsọ sí i. Ohun tí ó sọ ni pé, “Oluwa yóo bá ọ wí.”

10 Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi a máa sọ ìsọkúsọ nípa ohunkohun tí kò bá ti yé wọn. Àwọn nǹkan tí ó bá sì yé wọn, bí nǹkan tíí yé ẹranko ni. Ohun tí ń mú ìparun bá wọn nìyí.

11 Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun.

12 Bàsèjẹ́ ni wọ́n jẹ́ ninu àsè ìfẹ́ ìjọ, wọn kò ní ọ̀wọ̀ nígbà tí ẹ bá jọ ń jẹ, tí ẹ jọ ń mu. Ara wọn nìkan ni wọ́n ń tọ́jú bí olùṣọ́-aguntan tí ń tọ́jú ara rẹ̀ dípò aguntan. Wọ́n dàbí ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń gbá kiri tí kò rọ òjò. Igi tí kò ní èso ní àkókò ìkórè ni wọ́n, wọ́n ti kú sára. Nígbà tí ó bá ṣe, wọn á wó lulẹ̀ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.

13 Ìgbì omi òkun líle ni wọ́n, tí ó ń rú ìwà ìtìjú wọn jáde. Ìràwọ̀ tí kò gbébìkan ni wọ́n. Ààyè wọn ti wà nílẹ̀ fún wọn, ninu òkùnkùn biribiri títí ayé ainipẹkun.

14 Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́,

15 láti ṣe ìdájọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá. Yóo bá gbogbo àwọn eniyan burúkú wí fún gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n ti hù, ati gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bẹ̀rù Ọlọrun ti sọ sí òun Oluwa.”