1 Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí.Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn,
2 ati ìrètí ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun tí kì í purọ́ ti ṣèlérí láti ayérayé.
3 Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn ní àkókò tí ó wọ̀ fún un ninu iwaasu tí ó ti fi lé mi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ọlọrun Olùgbàlà wa.
4 Mò ń kọ ìwé yìí sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ ninu ẹ̀sìn igbagbọ kan náà.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Olùgbàlà wa, wà pẹlu rẹ̀.
5 Ìdí tí mo ṣe fi ọ́ sílẹ̀ ní Kirete ni pé kí o ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó kù tí kò dára tó, kí o sì yan àwọn àgbà lórí ìjọ ní gbogbo ìlú, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlànà fún ọ.