2 Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò.
3 Nítorí nígbà kan rí, àwa náà ń ṣe wérewère, à ń ṣe àìgbọràn, ayé ń tàn wá jẹ, a jẹ́ ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a sì ń jẹ ayé ìjẹkújẹ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. À ń hùwà ìkà ati ìlara. A jẹ́ ohun ìríra fún àwọn eniyan. Àwa náà sì kórìíra ọmọnikeji wa.
4 Ṣugbọn nígbà tí Ọlọrun fi inú rere ati ìfẹ́ rẹ̀ sí àwa eniyan hàn, ó gbà wá là;
5 kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun.
6 Ó da Ẹ̀mí yìí lé wa lórí lọpọlọpọ láti ọwọ́ Jesu Kristi Olùgbàlà wa.
7 Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun.
8 Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí.Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani.