13 Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin.
14 Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa,
15 A! fun ọjọ na, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ, ati bi iparun lati ọwọ́ Olodumare ni yio de.
16 A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa?
17 Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ.
18 Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro.
19 Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ.