16 Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀.
17 Jẹ ki awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, sọkun lãrin iloro ati pẹpẹ, si jẹ ki wọn wi pe, Dá awọn enia rẹ si, Oluwa, má si ṣe fi iní rẹ fun ẹ̀gan, ti awọn keferi yio fi ma jọba lori wọn: ẽṣe ti nwọn o fi wi ninu awọn enia pe, Ọlọrun wọn há da?
18 Nigbana ni Oluwa yio jowú fun ilẹ rẹ̀, yio si kãnu fun enia rẹ̀.
19 Nitõtọ, Oluwa yio dahùn, yio si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, Wò o emi o rán ọkà, ati ọti-waini, ati ororo si nyin, a o si fi wọn tẹ́ nyin lọrùn: emi kì yio si fi nyin ṣe ẹ̀gan mọ lãrin awọn keferi.
20 Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla.
21 Má bẹ̀ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ̀: nitori Oluwa yio ṣe ohun nla.
22 Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn.