4 Irí wọn dàbi irí awọn ẹṣin; ati bi awọn ẹlẹṣin, bẹ̃ni nwọn o sure.
5 Bi ariwo kẹkẹ́ lori oke ni nwọn o fò, bi ariwo ọwọ́-iná ti o jó koriko gbigbẹ, bi alagbara enia ti a tẹ́ ni itẹ́gun.
6 Li oju wọn, awọn enia yio jẹ irora pupọ̀: gbogbo oju ni yio ṣú dùdu.
7 Nwọn o sare bi awọn alagbara; nwọn o gùn odi bi ọkunrin ologun; olukuluku wọn o si rìn lọ li ọ̀na rẹ̀, nwọn kì yio si bà ọ̀wọ́ wọn jẹ.
8 Bẹ̃ni ẹnikan kì yio tì ẹnikeji rẹ̀; olukuluku wọn o rìn li ọ̀na rẹ̀: nigbati nwọn ba si ṣubu lù idà, nwọn kì o gbọgbẹ́.
9 Nwọn o sure siwa sẹhin ni ilu: nwọn o sure lori odi, nwọn o gùn ori ile; nwọn o gbà oju fèrese wọ̀ inu ile bi olè.
10 Aiye yio mì niwaju wọn; awọn ọrun yio warìri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhìn.