3 Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.
4 Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
5 Nitoriti ẹnyin ti mu fàdakà mi ati wurà mi, ẹnyin si ti mu ohun rere daradara mi lọ sinu tempili nyin:
6 Ati awọn ọmọ Juda, ati awọn ọmọ Jerusalemu li ẹnyin ti tà fun awọn ara Griki, ki ẹnyin ba le sìn wọn jina kuro li agbègbe wọn.
7 Kiyesi i, emi o gbe wọn dide kuro nibiti ẹnyin ti tà wọn si, emi o si san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
8 Emi o si tà awọn ọmọkunrin nyin ati awọn ọmọbinrin nyin si ọwọ́ awọn ọmọ Juda, nwọn o si tà wọn fun awọn ara Sabia, fun orilẹ-ède kan ti o jinà rére, nitori Oluwa li o ti sọ ọ.
9 Ẹ kede eyi li ãrin awọn keferi; ẹ yà ogun si mimọ́, ẹ ji awọn alagbara, ẹ sunmọ tòsi, ẹ goke wá gbogbo ẹnyin ọkunrin ologun.