4 Nitoripe a o kọ̀ Gasa silẹ, Aṣkeloni yio si dahoro: nwọn o le Aṣdodu jade li ọsangangan, a o si fà Ekronu tu kuro.
5 Egbe ni fun awọn ẹniti ngbe agbègbe okun, orilẹ-ède awọn ara Kereti! ọ̀rọ Oluwa dojukọ nyin; iwọ Kenaani, ilẹ awọn ara Filistia, emi o tilẹ pa ọ run, ti ẹnikan kì yio gbe ibẹ̀ mọ.
6 Agbègbe okun yio si jẹ ibujoko ati agọ fun awọn olùṣọ agùtan, ati agbo fun agbo-ẹran.
7 Agbègbe na yio si wà fun iyokù ile Juda; nwọn o jẹ̀ li ori wọn: ni ile Aṣkeloni wọnni ni nwọn o dùbulẹ li aṣãlẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbèkun wọn padà kuro.
8 Emi ti gbọ́ ẹgàn Moabu, ati ẹlẹyà awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti kẹgàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbe ara wọn ga si agbègbe wọn.
9 Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn.
10 Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoripe nwọn ti kẹgàn, nwọn si ti gbe ara wọn ga si enia Oluwa awọn ọmọ-ogun.