8 Emi ti gbọ́ ẹgàn Moabu, ati ẹlẹyà awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti kẹgàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbe ara wọn ga si agbègbe wọn.
9 Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn.
10 Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoripe nwọn ti kẹgàn, nwọn si ti gbe ara wọn ga si enia Oluwa awọn ọmọ-ogun.
11 Oluwa yio jẹ ibẹ̀ru fun wọn: nitori on o mu ki gbogbo òriṣa ilẹ aiye ki o rù; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ̀ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi.
12 Ẹnyin ara Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin.
13 On o si nà ọwọ́ rẹ̀ si ihà ariwa, yio si pa Assiria run; yio si sọ Ninefe di ahoro, ati di gbigbẹ bi aginjù.
14 Agbo-ẹran yio si dùbulẹ li ãrin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ède: ati ẹiyẹ òfu ati õrẹ̀ yio ma gbe atẹrigbà rẹ̀, ohùn wọn yio kọrin li oju fèrese; idahoro yio wà ninu iloro: nitoriti on o ṣi iṣẹ kedari silẹ.