1 EGBE ni fun ọlọ̀tẹ ati alaimọ́, fun ilu aninilara nì.
2 On kò fetisi ohùn na; on kò gba ẹkọ́; on kò gbẹkẹ̀le Oluwa; on kò sunmọ ọdọ Ọlọrun rẹ̀.
3 Awọn olori rẹ̀ ti o wà lãrin rẹ̀ kiniun ti nke ramùramù ni nwọn; awọn onidajọ rẹ̀ ikõkò aṣãlẹ ni nwọn; nwọn kò sán egungun titi di owurọ̀.
4 Awọn woli rẹ̀ gberaga, nwọn si jẹ ẹlẹtàn enia: awọn alufa rẹ̀ ti ba ibi mimọ́ jẹ: nwọn ti rú ofin.
5 Oluwa li olõtọ lãrin rẹ̀, kì yio ṣe buburu: li orowurọ̀ li o nmu idajọ rẹ̀ wá si imọlẹ, kì itase; ṣugbọn awọn alaiṣõtọ kò mọ itìju.
6 Mo ti ke awọn orilẹ-ède kuro; ile giga wọn dahoro; mo sọ ita wọnni di ofo, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja ihà ibẹ̀: a pa ilu wọnni run, tobẹ̃ ti kò si enia kan, ti kò si ẹniti ngbe ibẹ̀.
7 Emi wipe, Lõtọ iwọ o bẹ̀ru mi, iwọ o gba ẹkọ́; bẹ̃ni a kì ba ti ke ibujoko wọn kuro, bi o ti wù ki mo jẹ wọn ni iyà to: ṣugbọn nwọn dide ni kùtukùtu, nwọn ba gbogbo iṣẹ wọn jẹ.