3 Awọn olori rẹ̀ ti o wà lãrin rẹ̀ kiniun ti nke ramùramù ni nwọn; awọn onidajọ rẹ̀ ikõkò aṣãlẹ ni nwọn; nwọn kò sán egungun titi di owurọ̀.
4 Awọn woli rẹ̀ gberaga, nwọn si jẹ ẹlẹtàn enia: awọn alufa rẹ̀ ti ba ibi mimọ́ jẹ: nwọn ti rú ofin.
5 Oluwa li olõtọ lãrin rẹ̀, kì yio ṣe buburu: li orowurọ̀ li o nmu idajọ rẹ̀ wá si imọlẹ, kì itase; ṣugbọn awọn alaiṣõtọ kò mọ itìju.
6 Mo ti ke awọn orilẹ-ède kuro; ile giga wọn dahoro; mo sọ ita wọnni di ofo, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja ihà ibẹ̀: a pa ilu wọnni run, tobẹ̃ ti kò si enia kan, ti kò si ẹniti ngbe ibẹ̀.
7 Emi wipe, Lõtọ iwọ o bẹ̀ru mi, iwọ o gba ẹkọ́; bẹ̃ni a kì ba ti ke ibujoko wọn kuro, bi o ti wù ki mo jẹ wọn ni iyà to: ṣugbọn nwọn dide ni kùtukùtu, nwọn ba gbogbo iṣẹ wọn jẹ.
8 Nitorina ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ na ti emi o dide si ohun-ọdẹ: nitori ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ède jọ, ki emi ki o le kó awọn ilẹ ọba jọ, lati dà irúnu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owu mi jẹ gbogbo aiye run.
9 Nitori nigbana li emi o yi ède mimọ́ si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma pè orukọ Oluwa, lati fi ọkàn kan sìn i.