20 Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun.
21 Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:
22 Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀:
23 Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ:
24 Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada.
25 Nitori ẹnyin ti nṣako lọ bi agutan, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin pada si ọdọ Oluṣọ-agutan ati Biṣopu ọkàn nyin.