8 Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu.
9 Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:
10 Ẹnyin ti kì iṣe enia nigbakan rí, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin di enia Ọlọrun, ẹnyin ti kò ti ri ãnu gbà ri, ṣugbọn nisisiyi ẹ ti ri ãnu gbà.
11 Olufẹ, mo bẹ̀ nyin, bi alejò ati bi èro, lati fà sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ti mba ọkàn jagun;
12 Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.
13 Ẹ mã tẹriba fun gbogbo ìlana enia nitori ti Oluwa: ibãṣe fun ọba, bi fun olori;
14 Tabi fun awọn bãlẹ, bi fun awọn ti a rán lati ọdọ rẹ̀ fun igbẹsan lara awọn ti nṣe buburu, ati fun iyìn awọn ti nṣe rere.