1 JUDA, iranṣẹ Jesu Kristi, ati arakunrin Jakọbu, si awọn ti a pè, olufẹ ninu Ọlọrun Baba, ti a si pamọ́ fun Jesu Kristi:
2 Ki ãnu, ati alafia, ati ifẹ ki o mã bi si i fun nyin.
3 Olufẹ, nigbati mo fi aisimi gbogbo kọwe si nyin niti igbala ti iṣe ti gbogbo enia, nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki n si gbà nyin niyanju lati mã ja gidigidi fun igbagbọ́, ti a ti fi lé awọn enia mimọ́ lọwọ lẹ̃kanṣoṣo.
4 Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.