4 Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.
5 Njẹ emi nfẹ lati rán nyin leti bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ gbogbo rẹ̀ lẹ̃kan ri, pe Oluwa, nigbati o ti gbà awọn enia kan là lati ilẹ Egipti wá, lẹhinna o run awọn ti kò gbagbọ́.
6 Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì.
7 Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.
8 Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá.
9 Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi.
10 Ṣugbọn awọn wọnyi nsọ̀rọ-òdi si ohun gbogbo ti nwọn kò mọ̀: ṣugbọn ohun gbogbo ti nwọn mọ̀ nipa ẹda, bi ẹranko tí kò ni iyè, ninu nkan wọnyi ni nwọn di ẹni iparun.