Ẹkún Jeremáyà 1:1-6 BMY

1 Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,tí ó wà nípò opó,Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọba bìnrin láàrin ìlúni ó padà di ẹrú.

2 Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sunkún kíkoròpẹ̀lú omijé tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀wọ́n ti di alátakò rẹ̀.

3 Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,Júdà lọ sí àjòÓ tẹ̀dó láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.Àwọn tí ó ń tẹ̀le ká a mọ́ibi tí kò ti le sá àṣálà.

4 Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Ṣíónì ń sọ̀fọ̀,nítorí kò sẹ́ni tí ó wá láti jọ́sìn.Ẹnu bodè pátapáta ni ó dahoro,àwọn Olórí àlùfáà ibẹ̀ kérora,àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ sì ń kẹ́dùn,òun gan-an wà pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn.

5 Aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

6 Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé.Àwọn ọmọ ọba kùnrin dàbí i ìgalàtí kò rí ewé tútù jẹ;nínú àárẹ̀ wọ́n sáréníwájú ẹni tí ó ń lé wọn.