Ẹkún Jeremáyà 5 BMY

1 Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

2 Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,ilé wa ti di ti àjèjì.

3 Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,àwọn ìyá wa ti di opó.

4 A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;igi wa di títà fún wa.

5 Àwọn tí ó ń lé wa sún mọ́ wa;àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

6 Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Éjíbítì àti Ásíríàláti rí oúnjẹ tótó jẹ.

7 Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì sí mọ́,àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8 Àwọn ẹrú ń jọba lórí wa,kò sì sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9 Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wanítorí idà tí ó wà ní ihà.

10 Ẹran ara wa gbóná bí ààrò,ebi sì yó wa bí àárẹ̀.

11 Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lò pọ̀ ní Síónì,àti àwọn wúndíá wa ní ìlú Júdà.

12 Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di ṣíṣo sókè ní ọwọ́ wọn;kò sí ìbọ̀wọ̀ fágbà mọ́.

13 Àwọn ọdọ́mọkùnrin wa ru òkúta;àwọn ọmọkùnrin sì ńṣsàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

14 Àwọn àgbààgbà ti lọ kúrò ní ẹnu bodè ìlú;àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn

15 Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.

16 Adé ti sí kúrò ní orí waÈgbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.

17 Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.

18 Fún òkè Síónì tí ó ti di ahorolórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

19 Ìwọ, Olúwa, jọba títí láé;ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

20 Kí ló dé tí o n gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

21 Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbà a nì

22 Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátátí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.

orí

1 2 3 4 5