Ẹkún Jeremáyà 1:16-22 BMY

16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sunkúntí omijé sì ń dà lójú mi,Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sími,kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.Àwọn ọmọ mi di aláìnínítorí ọ̀ta ti borí.”

17 Ṣíónì na ọwọ́ jáde,ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. Olúwa ti pàṣẹ fún Jákọ́bùpé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀ta fún unJérúsálẹ́mù ti diohun aláìmọ́ láàrin wọn.

18 “Olóòtítọ́ ni Olúwa,ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;ẹ wò mí wò ìyà mi.Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mini a ti kó lọ sí ìgbèékùn.

19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ miṣùgbọ́n wọ́n tàn mí.Àwọn olórí àlùfáà àti àgbààgbà miṣègbé sínú ìlúnígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹtí yóò mú wọn wà láàyè.

20 “Olúwa, wòó, bí mo ti wà nínú ìnira!Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,ìdààmú dé bá ọkàn minítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.Ní gbangba ni idà ń parun;ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,kí wọ́n le dàbí tèmi.

22 “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;jẹ wọ́n níyàbí o se jẹ mí níyànítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.Ìrora mi pọ̀ọkàn mi sì káàárẹ̀.”