1 Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Síónìpẹ̀lú ìkúùkù ìbínú rẹ̀!Ó sọ ògo Ísírẹ́lì kalẹ̀Láti ọ̀run sí ayé;kò rántí àpótí-ìtìṣẹ̀ rẹ̀ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
2 Làìní àánú ni Olúwa gbéibùgbé Jákọ́bù mì;nínú ìrunú rẹ̀ ni ó wóibi gíga ọmọbìnrin Júdà lulẹ̀.Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ aládé ọkùnrinlọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.
3 Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó kégbogbo ìwo Ísírẹ́lì.Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrònígbà tí àwọn ọ̀tá dé.Ó run ní Jákọ́bù bí ọ̀wọ́ inání àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Síónì.
4 Ó na ọfà rẹ̀ bí ọtá;ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múraBí ti ọ̀ta tí ó ti parunó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí inásórí àgọ́ ọmọbìnrin Síónì.