Ẹkún Jeremáyà 2:3-9 BMY

3 Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó kégbogbo ìwo Ísírẹ́lì.Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrònígbà tí àwọn ọ̀tá dé.Ó run ní Jákọ́bù bí ọ̀wọ́ inání àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Síónì.

4 Ó na ọfà rẹ̀ bí ọtá;ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múraBí ti ọ̀ta tí ó ti parunó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí inásórí àgọ́ ọmọbìnrin Síónì.

5 Olúwa dà bí ọ̀tá;ó gbé Ísírẹ́lì mì.Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mìó pa ibi gíga rẹ̀ run.Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀fún àwọn ọmọbìnrin Júdà.

6 Ó mú ìparun bá ibimímọ́,ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. Olúwa ti mú Síónì gbàgbéọjọ́ àṣè àti ọ̀ṣẹ̀ tí ó yàn;nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó runọba àti olórí àlùfáà.

7 Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.Ó sì fi lé ọ̀ta lọ́wọ́àwọn odi ààfin rẹ̀;wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwagẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìpèjẹ tí a yàn.

8 Olúwa pinnu láti faògiri tí ó yí ọmọbìnrin Síónì ya.Ó gbé wọn sórí òṣùnwọ̀n,kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.Ó mú kí ilé-ìsọ́ àti odi rẹ̀ sọ̀fọ̀wọ́n ṣòfò papọ̀.

9 Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,kò sí òfin mọ́,àwọn wòlíì rẹ̀ kò ríìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.