1 Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njúpẹ̀lú ọ̀pá ìbínú.
2 Ó ti lémi jáde ó sì mú mi rìnnínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀;
3 Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí misíwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
4 Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran ara mi gbóó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
5 Ó ti fi mí sí ìgbèkùn ó sì ti yí mi kápẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
6 Ó mú mi gbé nínú òkùnkùnbí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
7 Ó ti tì mí mọ́lé nítorí náà n kò le è sálọ;ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀