13 Ó fa ọkàn mí yapẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
14 Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn ènìyàn mi;wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
15 Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkoròàti ìdààmú bí omi.
16 Ó ti fi òkúta kán ẹyín mi;ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
17 Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;Mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18 Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọàti ìrètí mi nínú Olúwa.”
19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,ìkorò àti ìbànújẹ́.