20 Mo ṣèrántí wọn,ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkànàti nítorí náà ní mo nírètí.
22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,nítorí àánú rẹ kì í kùnà.
23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́
25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,sí àwọn tí ó ń wá a.
26 Ó dára kí a ní ṣùúrùfún ìgbàlà Olúwa.