23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́
25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,sí àwọn tí ó ń wá a.
26 Ó dára kí a ní ṣùúrùfún ìgbàlà Olúwa.
27 Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgànígbà tí ó wà ní èwe.
28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́,nítorí Olúwa ti fi fún un.
29 Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku—ìrètí sì lè wà.