28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́,nítorí Olúwa ti fi fún un.
29 Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku—ìrètí sì lè wà.
30 Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
31 Ènìyàn kò di ìtanùlọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
32 Lóòtọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,nítorí náà títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33 Nítorí kò mọ̀ọ́mọ̀ mú ìpọ́njú wátàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
34 Kí ó tẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.