44 Ìwọ ti fi ìkuukù bo ara rẹpé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtànláàrin orílẹ̀ èdè gbogbo.
46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọngbòòrò sí wa.
47 Àwa ti jìyà àti ìparun,nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48 Omijé ń ṣàn ní ojú mi bí odònítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
49 Ojú mi kò dá fún omijé,láì sinmi,
50 títí ìgbà tí Olúwa síjú wolẹ̀láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.