1 Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,wúrà dídára di àìdán!Òkúta ibi mímọ́ wá túkásí oríta gbogbo òpópó.
2 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Síónì tí ó ṣe iyebíye,tí wọ́n wọn iye wúrà ṣewá dàbí ìkòkò amọ̀ lásániṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!
3 Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aṣálẹ̀.
4 Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹṢùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn.