13 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíìàti àìṣedédé àwọn olórí àlùfáà,tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodosílẹ̀ láàrin rẹ̀.
14 Nísinsìnyí wọ́n ń rìn kiri ní òpópóbí ọkùnrin tí ó fọ́jú.Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́ntí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.
15 “Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.“Ẹlọ! Ẹlọ! Ẹ má se fọwọ́ kàn wá!”Àwọn ènìyàn láàrin orílẹ̀ èdè wí pé,“Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”
16 Olúwa ti tú wọn ká fún-ra-ra-rẹ̀;kò sí bojú tó wọn mọ́.Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,àti àánú fún àwọn àgbà.
17 Síwájú sí i, ojú wa kùnàfún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wòfún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.
18 Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níyenítorí òpin wa ti dé.
19 Àwọn tí ń lé wa yáraju idì ojú ọ̀run lọ;wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkèwọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní ihà.