2 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Síónì tí ó ṣe iyebíye,tí wọ́n wọn iye wúrà ṣewá dàbí ìkòkò amọ̀ lásániṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!
3 Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aṣálẹ̀.
4 Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹṢùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn.
5 Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradáradi òtòsì ní òpópó.Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ni wọ́n sùn ní orí òkítì eérú.
6 Ìjìyà àwọn ènìyàn mitóbi ju ti Sódómù lọ,tí a sí nípò ní òjijìláì sí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.
7 Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò dídì,wọ́n sì funfun ju wàrà lọlára, wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,ìrísí wọn dàbí sáfírè.
8 Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí wọ́n dúdú ju èédú;wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.Ara wọn hun mọ́ egungun;ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.