11 Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni ibùgbé wọn,pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.
12 Ní ìrúnú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.
13 Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là;Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,fifi ìpìlẹ̀ hàn títí dé ọrùn
14 pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹnígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀jáde láti tú wá ká:ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ talákà run ní kọ̀kọ̀.
15 Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn òkun já,O tẹ òkun mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀,ìwọ fi àwọn ẹsin rẹ̀ rin òkun já,ó sì mu omi ńlá jáde okiki omi ńlá
16 Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,ẹ̀sẹ̀ mi sì wárìrì,mo dúró ni ìdákẹ́jẹ́ fún ọjọ́ ìdààmúláti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,tí èso kò sí nínú àjàrà;tí iṣẹ igi olifi yóò jẹ́ àṣedànù,àwọn oko ki yóò sì mú oúnjẹ wá;tí a ṣi ke agbo ẹran kúrò nínú agbo,tí ki yóò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùsọ̀ mọ́,