4 Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì lè tẹ́ṣíwájú” ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.
5 “Májẹ̀mu mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mu ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á.
6 Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ídúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
7 “Nítorí ètè àlùfáà ní a ti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni iransẹ Olúwa àwọn ọmọ ogun.
8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Léfì jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.
9 “Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúṣàájú nínú òfin.”
10 Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhùwà àrékérekè olúkulùkù sí arákùnrin rẹ̀?