Málákì 1 BMY

1 Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀: ọ̀rọ̀ Olúwa sí Ísírẹ́lì láti ẹnu Málákì.

Ọlọ́run Fẹ́ràn Jákọ́bù, Ó Sì Kórìíra Ísọ̀

2 “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni Olúwa wí.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’“Ísọ̀ kì í ha ṣe arákùnrin Jákọ́bù bí?” ni Olúwa wí. “Ṣíbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jákọ́bù,

3 ṣùgbọ́n Ísọ̀ ni èmi kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè-ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akáta ihà.”

4 Édómù lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.”Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé: “Àwọ́n lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní Ilẹ̀ Búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú Olúwa.

5 Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni Olúwa, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Ísírẹ́lì.’

Ẹbọ Àìmọ́

6 “Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ-ọ̀dọ̀ a sì máa bọlá fún ọ̀gá rẹ̀. Bí èmí bá jẹ́ baba ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí mi dà? Bí èmi bá sì jẹ́ ọ̀gá ọlá, tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ ọ̀ mi.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ ọ̀ rẹ?’

7 “Ẹ̀yín gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ ẹ̀ mi.“Ẹ̀yín sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’“Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn.

8 Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé ìyẹn kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúkùnún àti aláìsàn ẹran rúbọ, ṣé ìyẹn kò ha bògìrì bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rúbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

9 “Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

10 “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrin yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ ọ yín.

11 Orúkọ mi yóò tóbi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀ oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ ọ̀ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

12 “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ́ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn.

13 Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.“Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó farapa, arọ àti olókùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rúbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí.

14 “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹ̀ran tó lábùkù rúbọ sí Olúwa; nítorí Ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.

orí

1 2 3 4