Málákì 2:8-14 BMY

8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Léfì jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

9 “Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúṣàájú nínú òfin.”

10 Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhùwà àrékérekè olúkulùkù sí arákùnrin rẹ̀?

11 Júdà ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Ísírẹ́lì àti ni Jérúsálẹ́mù: nítorí Júdà tí ṣe eyi ti ó lè sọ ibi mímọ́ Olúwa di aláìmọ́ nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó.

12 Ní ti ẹni tí ó se èyí, ẹni tí ó wù kí ó jẹ, kí Olúwa kí ó gé e kúrò nínú àgọ́ Jákọ́bù, bí ó tilẹ̀ mú ẹbọ ọrẹ wá fún Olúwa àwọn ọmọ ogun.

13 Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì tún ṣe: Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ Olúwa mọ́lẹ̀. Ẹ̀yín sọkún, ẹ̀yín sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín.

14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti láàrin aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn síi: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkeji rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ.