5 “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe dù ú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lara, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àlejò rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.
6 “Èmi Olúwa kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù.
7 Láti ọjọ́ àwọn baba-ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò se padà?’
8 “Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’“Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ.
9 Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀ èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè.
10 Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ báà lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́ sílẹ̀ jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì àyè láti gbà á.
11 Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.