Rúùtù 3:11-17 BMY

11 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́ ní obìnrin oníwà rere.

12 Nítòótọ́ ni wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó sún mọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó sún mọ́ ọ ju ti tèmi lọ.

13 Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láàyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”

14 Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n, ó dìde ní ìdájí kùtùkùtù kí ẹnìkín-ín-ní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Bóásì sì sọ fún-un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀-ìpakà.”

15 Ó sì tún wí fún-un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rúùtù sì ṣe bẹ́ẹ̀, Bóásì sì wọn òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìgboro.

16 Nígbà tí Rúùtù dé ilé, Náómì, ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí, ọmọbìnrin mi?”Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún-un, fún ìyá ọkọ rẹ̀.

17 Ó fi kún-un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà.’ ”