Rúùtù 3 BMY

Rúùtù Àti Bóásì Ní Ilẹ̀ Ìpakà

1 Ní ọjọ́ kan, Nóámì, ìyá ọkọ Rúùtù wí fún-un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn fún ọ, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ?

2 Wòó, Bóásì ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà ní ilẹ̀-ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí.

3 Wẹ̀, kí o sì fi ìpara-olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán.

4 Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o sí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn síbi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”

5 Rúùtù sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”

6 Bẹ́ẹ̀ ni Rúùtù lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún-un, pé kí o se.

7 Nígbà tí Bóásì parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà bálì tí wọ́n kó jọ. Rúùtù yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó sí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

8 Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárin òru, ẹ̀rú bàá, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

9 Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?”Rúùtù sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rúùtù, ìránṣẹ́-bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”

10 Bóásì sì wí fún-un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fi hàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí talákà.

11 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́ ní obìnrin oníwà rere.

12 Nítòótọ́ ni wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó sún mọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó sún mọ́ ọ ju ti tèmi lọ.

13 Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láàyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”

14 Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n, ó dìde ní ìdájí kùtùkùtù kí ẹnìkín-ín-ní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Bóásì sì sọ fún-un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀-ìpakà.”

15 Ó sì tún wí fún-un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rúùtù sì ṣe bẹ́ẹ̀, Bóásì sì wọn òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìgboro.

16 Nígbà tí Rúùtù dé ilé, Náómì, ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí, ọmọbìnrin mi?”Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún-un, fún ìyá ọkọ rẹ̀.

17 Ó fi kún-un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà.’ ”

18 Náómì sì wí fún-un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí. Nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”

orí

1 2 3 4