1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefanáyà ọmọ Kúsì, ọmọ Gédálíyà, ọmọ Ámáríyà, ọmọ Heṣekáyà, ní ìgbà Jósíà ọmọ Ámónì ọba Júdà.
2 “Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúròlórí ilẹ̀ náà pátapáta,”ni Olúwa wí.
3 “Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹrankokúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojúọ̀run kúrò àti ẹja inú òkun, àtiohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọnènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”ni Olúwa wí
4 “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Júdààti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Báálì, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣàpẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,
5 àti àwọn tí wọn ń foríbalẹ̀ tí wọnń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé.Àwọn tí wọn ń sìn, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,tí wọ́n sì ń fi Mólékì búra.
6 Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.
7 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run,nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Olúwa ti pèṣè ẹbọ kan sílẹ̀,ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.