Sefanáyà 2 BMY

1 Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọpọ̀orílẹ̀ èdè tí kò ní ìtìjú,

2 kí a tó lé yín kúrò bí èrò ìyàngbò ọkà,kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kíọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.

3 Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà,ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pa láṣẹ.Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú,bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.

Ìlòdì Sí Fílísítíà

4 Nítorí pé, a ó kọ Gásà sílẹ̀,Áṣíkélónì yóò sì dahoro.Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Áṣídódù jáde,a ó sì fa Ékírónì tu kúrò.

5 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ̀yin ènìyàn ara Kérétì;Ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kénánì,ilẹ̀ àwọn ara Fílísítíà.Èmi yóò pa yín run,ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín;

6 Ilẹ̀ náà ní etí òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kérétì,ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.

7 Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Júdà,níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí ìjẹ fún ẹran,Ní ilé Áṣíkélónì ni wọn yóòdùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bojútó wọn,yóò sì yí ìgbékùn wọn padà.

Ìlòdì Sí Móábù Àti Ámónì

8 “Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Móábù,àti ẹlẹ́yà àwọn Ámónì,àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn.

9 Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”ni Olúwa Sódómù wí, Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì,“Ní tòótọ́ Móábù yóò dàbí Sódómùàti Ámónì yóò sì dàbí Gòmórà,ibi tí ó kún fún yèrèpèàti ihó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.Ìyòókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi niyóò jogún ilẹ̀ wọn.”

10 Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa alágbára ṣe ẹlẹ́yà.

11 Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn;nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣa ilẹ̀ náà run.Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn,olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.

12 “Ẹ̀yin Etiópíà pẹ̀lú,a ó fi idà mi pa yín.”

13 Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá,yóò sì pa Ásíríà run,yóò sì sọ Nínéfè di ahoro,àti di gbígbẹ bí ihà.

14 Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ṣíbẹ̀àti gbogbo ẹ̀dá ní orísìírísìí.Òwìwí ihà àti dídún bí ẹyẹ òwìwíyóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ́n rẹ̀.Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé,ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu ọ̀nà,òun yóò sì ṣẹ́ kédárì sílẹ̀.

15 Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu.Ó sì sọ sí ara rẹ̀ pé,“Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.”Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́,ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó!Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀yóò fi rẹ́rìnín ẹlẹ́yà,wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.

orí

1 2 3