12 Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà,èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kantí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
13 Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún,àti ilé wọn yóò sì run.Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́nwọn kì yóò gbé nínú ilé náà,wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtíWáìnì láti inú rẹ̀.
14 “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkúnàwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,
15 ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoroọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,ọjọ́ kuru àti òkùnkùn biribiri,
16 ọjọ́ òpè àti ìdágìrì àti ìdágirisí àwọn ìlú olódìàti sí àwọn ìsá gíga
17 Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sóríènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú,nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa.Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí erukuàti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.
18 Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọnkì yóò sì le gbà wọ́n làní ọjọ́ ìbínú Olúwa.Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi ináìjowú rẹ̀ parun,nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sígbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé ayé.”