8 Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa,Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọnọmọ ọba ọkùnrin,pẹ̀lú gbogboàwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.
9 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹgbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu ọ̀nà,tí wọ́n sì kún tẹ́ḿpìlì Olúwa wọnpẹ̀lú ìwà-ipá àti ẹ̀tàn.
10 “Ní sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja,híhu láti ìhà kejì wá àtiariwo ńlá láti òkè kékeré wá.
11 Hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà,gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.
12 Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà,èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kantí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
13 Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún,àti ilé wọn yóò sì run.Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́nwọn kì yóò gbé nínú ilé náà,wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtíWáìnì láti inú rẹ̀.
14 “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkúnàwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,