1 Jòhánù 2 BMY

1 Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jésù Kírísítì, olódodo nìkan.

2 Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.

3 Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́.

4 Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì sí nínú rẹ̀.

5 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀.

6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti rìn.

7 Ẹ̀yin olùfẹ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́.

8 Pẹ̀lúpẹ̀lú, òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín; èyí tí í ṣe òtítọ́ nínú rẹ̀ àti nínú yin, nítorí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ́ òtítọ́ sì tí ń tàn.

9 Ẹni tí o bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí o sì kóríra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn.

10 Ẹni tí o ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, o ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kóríra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkunkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.

12 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n,nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.

13 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe,Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n,nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba.

14 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètékọṣe.Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,nítorí tí ẹ̀yin ni agbára,tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín,tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.

Ẹ Má Ṣe Fẹ́ràn Ayé

15 Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀.

16 Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kùfẹ́ ẹni ẹ̀sẹ̀, ìfẹ́kùfẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó se: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.

17 Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kùfẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.

Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Asòdìsí-Kírísítì

18 Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé Aṣòdìsí-Kírísítì ń bọ̀ wá, àní nísìnsin yìí, púpọ̀ Aṣòdì-sí-Kírísítì ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fí mọ́ pé ìgbà ìkẹ́yìn ni èyí.

19 Wọn ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró: ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa.

20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfòróró-yàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí-mímọ́ wá, gbogbo yín sì mọ òtítọ́.

21 Èmi kò kọ̀wé sí yín nítorí pé ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, àti pé kò sí èké nínú òtítọ́.

22 Ta ni èké? Ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù kì í ṣe Kírísítì. Eléyìí ni Aṣòdìsí-Kírísítì: ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ.

23 Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba; ṣùgbọ́n ẹni tí o ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú.

24 Ẹ jẹ́ kí èyí tí ẹ tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe máa gbé inú yín. Bí èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin ó sì dúró nínú Ọmọ àti nínú Baba.

25 Èyí sì ni ìlérí náà tí ó tí ṣe fún wa, àní ìyè àìnípẹ̀kun.

26 Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé sí yín ní ti àwọn tí wọ́n fẹ́ kó o yín sìnà.

27 Ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀yin ìfóróró-yàn tí gba lọ́wọ́ rẹ̀ sì ń gbé inú yín, ẹ̀yin kò tún nílò pé kí ẹnìkan kọ yín. Ṣùgbọ́n bí ìfòróró-yàn náà ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo tí o jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe èké, àní gẹ́gẹ́ bí ó sì ti kọ́ yín, ẹ máa gbé inú rẹ̀.

Àwọn Ọmọ Ọlọ́run

28 Àti nísinsin yìí, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ẹ máa gbé inú rẹ̀, pé nígbà tí òun ó bá farahàn, kí a lè ni ìgboyà níwájú rẹ̀, kí ojú má sì tì wá níwájú rẹ̀ ni ìgbà wíwá rẹ̀.

29 Bí ẹ̀yin ba mọ́ pé olódodo ni òun, ẹ mọ pé a bí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe òdodo nípa rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5