1 Pọ́ọ̀lù, Sílásì àti Tímótíù.A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jésù Kírísítì.Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kírísítì kí ó jẹ́ tiyín.
2 Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú.
3 A ń rántí lí àìsinmi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Bàbá iṣẹ́ ìgbàgbọ́yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró sinsin ìretí yín nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.
4 Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀.
5 Nítorí pé, nígbà tí a mú ìyìn rere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrin yín nítorí yín.
6 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mi Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín.
7 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹrẹ fún gbogbo àwọn Kírísírẹ́nì tó wà ní agbégbé Makedóníà àti Ákáyà.