17 Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín.
18 Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n Èṣù ú dè wá lọ́nà.
19 Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó sògo níwájú Jésù Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ ní?
20 Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.