1 Tẹsalóníkà 2:9-15 BMY

9 Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn-án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnìkẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín.

10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrin ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

11 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀

12 ìyànjú, ìtùnnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkararẹ̀.

13 Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

14 Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́se àwọn ìjọ tí o wà ní Jùdíà jẹ. Bí a ti gbógun tì wọ́n, láti ọwọ́ àwọn ará ìlú wọn (àwọn Júù), bẹ́ẹ̀ ni a gbógun ti ẹ̀yin pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù,

15 àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn