1 Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa sìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn.
2 Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àláfíà àti ìdákẹ́jẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.
3 Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olúgbàlà wa;
4 Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.
5 Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kírísítì Jésù ọkùnrin náà.
6 Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.
7 Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, Àpósítélì—òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.