8 Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn.
9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsí ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun-dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,
10 Bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.
11 Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́jẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́.
12 Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́jẹ́.
13 Nítorí Ádámù ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Éfà.
14 Ádámù kọ́ ni a tàn jẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀.