13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́-ara yìí.
14 Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́-ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní bí Olúwa wa Jésù Kírísítì ti fi hàn mí.
15 Èmi o sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi.
16 Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fí ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jésù Kírísítì Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí Ọlá-ńlá Rẹ̀ ni àwa jẹ́.
17 Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
18 Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà.
19 Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlìí dunjúdunjú síi, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsí gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ́ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín.