7 Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì.
8 Nítorí bí ẹ̀yín bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì.
9 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.
10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsinmi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò subú.
11 Nítorí bayìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísítì.
12 Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyìí nígbàgbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí.
13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́-ara yìí.