1 Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì ti Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.
2 Sí Tímótíù, Ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n:Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kírísítì Jésù Olúwa wa,
3 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn funfun gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsinmi lọ́sàn-án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi.
4 Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀.
5 Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìlẹ́tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá-ńlá rẹ, àti nínú Yùníìsì ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó da mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.